Ilé-ẹjọ́ ní kò le lọọ gbàtọ́jú lókè-òkun
By Kayọde Ọmọtọṣọ
Lanaa, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Mataima, Abuja, ni gomina ileefowopamọ agba ilẹ wa tẹlẹ, Godwin Emefiele, ko lẹtọọ lati lọọ gbatọju loke-okun. Adajọ Hamza Muazu, ni pe Emefield ko ko awọn ẹri to to silẹ lati fihan pe ewu wa fun un ti ko ba rinrinajo lọ soke-okun fun itọju ara rẹ.
Adajọ ni pe loootọ, Emefiele ni pe awọn dokita oun ranṣẹ pe oun fun itọju ṣugbọn ko fi iwe ti wọn fi ranṣẹ pe e ṣọwọ sile-ẹjọ gẹgẹ bi ẹri. Adajọ Muazu ni gomina tẹlẹ nileefowopamọ agba ilẹ wa yii ko fi ẹri kalẹ pe ko si ileewosan kankan lorileede Naijiria to le ṣetọju aisan to n ṣe e. Adajọ ni “ile-ẹjọ ọtọọtọ mẹta ni olujẹjọ ti n jẹjọ lọwọ lori ẹsun iwa ọdaran, idi niyẹn to fi yẹ ki ile-ẹjọ mọ idi to fi fẹẹ lọọ gbatọju ni pato, eyi ti ko fihan ile-ẹjọ titi di asiko yii. Nitori idi eyi, ẹbẹ olujẹjọ ko nitumọ rara, a si fagile e.”